Àwọn Ìfilọ̀
- Ìwé tá a máa lò ní March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! May àti June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, irú bíi, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú márùn-ún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde: Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?, Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? 
- Ọjọ́ Monday, April 14, 2014 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá jẹ́ ọjọ́ Monday ni ìjọ yín máa ń ṣèpàdé, kí ẹ ṣe é ní ọjọ́ míì tí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di dandan kẹ́ ẹ fagi lé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fi àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì lóṣù yẹn. 
- Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù March 2014, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ọlọ́run Máa Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Là Lọ́wọ́ Wàhálà Ayé.”