Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 27, 2014.
- Bó ṣe wà nínú Númérì 21:5, kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ráhùn sí Ọlọ́run àti Mósè, ìkìlọ̀ wo nìyẹn sì jẹ́ fún wa? [Sept. 1, w99 8/15 ojú ìwé 26 sí 27] 
- Kí nìdí tí ìbínú Jèhófà fi ru sí Báláámù? (Núm. 22:20-22) [Sept. 8, w04 8/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3] 
- Kí ni Númérì 25:11 sọ nípa ìwà tí Fíníhásì hù, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? [Sept. 8, w04 8/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5] 
- Àwọn ọ̀nà wo ni Mósè gbà fi àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ta yọ lélẹ̀ fún wa lónìí? (Núm. 27:5, 15-18) [Sept. 15, w13 2/1 ojú ìwé 5] 
- Báwo ni Jóṣúà àti Kálébù ṣe fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé àwọn èèyàn aláìpé lè rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí láìka inúnibíni sí? (Núm. 32:12) [Sept. 22, w93 11/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 13] 
- Tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè rí kọ́ látinú ìgbọràn àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì? (Núm. 36:10-12) [Sept. 29, w08 2/15 ojú ìwé 4 sí 5 ìpínrọ̀ 10] 
- Kí ni ìyọrísí ìráhùn àti ọ̀rọ̀ tí kò dára táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ, kí la sì rí kọ́ nínú ìtàn yìí? (Diu. 1:26-28, 34, 35) [Oct. 6, w13 8/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7] 
- Ohun méjì pàtàkì wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìbùkún Jèhófà gbà, kí nǹkan sì lè dára fún wọn ní Ilẹ̀ Ìlérí? (Diu. 4:9) [Oct. 13, w06 6/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 15] 
- Lọ́nà wo ni aṣọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi gbó tí ẹsẹ̀ wọn kò sì wú nígbà tí wọ́n ń rìn láginjù? (Diu. 8:3, 4) [Oct. 20, w04 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1] 
- Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Mósè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n “rọ̀ mọ́” Jèhófà sílò? (Diu. 13:4, 6-9) [Oct. 27, w02 10/15 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 14]