ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/14 ojú ìwé 8
  • Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 12/14 ojú ìwé 8

Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwa èèyàn Jèhófà máa ń dí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará wa ṣètò àkókò wọ́n láàárín oṣù August àti November kí wọ́n lè lọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé. Arábìnrin kan tó fi àkókò ìsinmi rẹ̀ wàásù níbẹ̀ sọ pé: “Látìgbà tí mo ti ń gba àkókò ìsinmi, èyí tí mo tíì gbádùn jù nìyí. Mi ò kábàámọ̀ rẹ̀ láé.” Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń pàdé àwọn èèyàn tí ebi tẹ̀mí ń pá tí wọ́n sì ń fẹ́ láti máa fi òdodo ṣèwà hù. Díẹ̀ lára àwọn ìrírí táwọn ará ní nìyí:

• Ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, àwùjọ àwọn akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] gbéra láti lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé tó wà ní Ìpínlẹ̀ Kogí. Wọ́n sọ pé: “Àwọn èèyàn méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] ló pésẹ̀ sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn tí a ṣe ní abúlé Ejuku. Lẹ́yìn tí àsọyé parí, a ṣèfilọ̀ pé kí àwọn tó bá fẹ́ kí a máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sí ọwọ́ iwájú. Sí ìyàlẹ́nu wa, àwọn èèyàn méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ló ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì mú sùúrù títí tá a fi kọ orúkọ, àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù wọn sílẹ̀.”

• Ìrírí tó kàn yìí fi bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe ń nípa lórí àwọn èèyàn hàn: Nígbà tí àwọn akéde méjì kan ń kọ́ ọmọdékùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níwájú ilé rẹ̀, wọ́n kíyè sí i pé àwọn obìnrin méjì kan ń jà torí owó. Ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà wà nínú oyún. Àwọn ará àdúgbò gbìyànjú láti bá wọn parí ìjà náà àmọ́ pàbó ni ìgbìyànjú wọn já sí. Aláboyún náà kúrò níbẹ̀ fúngbà díẹ̀, àmọ́ nígbà tó tún fẹ̀ pa dà sídìí ìjà náà ni àwọn akéde méjì náà bá lọ bá a sọ̀rọ̀. Wọ́n jẹ́ kó mọ jàǹbá tó lè ṣẹlẹ̀ sí òun àti ọmọ inú rẹ̀. Wọ́n sì tún jẹ́ kó mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí ọmọ tó wà nínú rẹ̀. (Ẹ́kís. 21:22-25) Ni obìnrin náà bá pinnu pé òun á gbójú fo owó náà dípò kí òun rí ìbínú Jèhófà. Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2013, igba ó lé mẹ́rìnlélógójì [244] àwùjọ tó ní nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ìrínwó ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [3,415] àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló kópa nínú ìpolongo náà. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ṣètò àkókò rẹ̀ kó o bàa lè kópa nínú ìpolongo tó ń bọ̀?—Sm. 110:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́