Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 23, 2015.
- Báwo ni àwọn ìlú ààbò lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe yàtọ̀ sí ibi ààbò àwọn kèfèrí tó wà fún àwọn ọ̀daràn tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn? (Jóṣ. 20:2, 3) [Jan. 5, w10 11/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 4 sí 6] 
- Kí nìdí tí Jóṣúà fi fi ìdánilójú sọ ọ̀rọ̀ tó wà ní Jóṣúà 23:14, kí sì nìdí tí àwa náà fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà? [Jan. 12, w07 11/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 19] 
- Nígbà tí wọ́n pín ilẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà Júdà ni wọ́n kọ́kọ́ sọ fún pé kó lọ máa gbé lórí ilẹ̀ tirẹ̀? (Oníd. 1:2, 4) [Jan. 19, w05 1/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5] 
- Kí nìdí tí Bárákì fi sọ pé dandan ni kí Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin bá òun lọ sójú ogun? (Oníd. 4:8) [Jan. 19, w05 1/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4] 
- Kí ni orúkọ tí Gídíónì fi pe pẹpẹ tó mọ fi hàn, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa? (Oníd. 6:23, 24) [Jan. 26, w14 2/15 ojú ìwé 22 àti 23 ìpínrọ̀ 9] 
- Kí la rí kọ́ látinú bí Gídíónì ṣe fún àwọn ẹ̀yà Éfúráímù tó fẹ́ bá a ṣe aáwọ̀ lésì? (Oníd. 8:1-3) [Feb. 2, w05 7/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4] 
- Nígbà tí Jẹ́fútà ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣé èèyàn ló ní lọ́kàn láti fi rúbọ? (Oníd. 11:30, 31) [Feb. 9, w05 1/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1] 
- Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Onídàájọ́ 11:35-37 ṣe sọ, kí ló jẹ́ kí ọmọbìnrin Jẹ́fútà mú ẹ̀jẹ́ bàbá rẹ̀ ṣẹ? [Feb. 9, w11 12/15 ojú ìwé 20 àti 21 ìpínrọ̀ 15 àti 16] 
- Nígbà tí kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì ‘ti olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà ní ojú tirẹ̀,’ ǹjẹ́ èyí dá wàhálà kankan sílẹ̀? Ṣàlàyé. (Oníd. 17:6) [Feb. 16, w05 1/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 7] 
- Ẹ̀kọ́ wo nípa bó ṣe yẹ ká tẹra mọ́ àdúrà gbígbà la rí kọ́ nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì oníwàkiwà ṣẹ́gun lẹ́ẹ̀mejì? (Oníd. 20:14-25) [Feb. 23, w11 9/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 sí 4]