ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 29-32
Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá
Bíi Ti Orí Ìwé
	Hesekáyà fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, ó sì ṣàṣeyọrí
- 746 sí 716 Ṣ.S.K. - Ìṣàkóso Hesekáyà 
- NÍSÀN 746 Ṣ.S.K. - Ọjọ́ 1 sí 8: Ó sọ àgbàlá inú lọ́hùn-ún di mímọ́ 
- Ọjọ́ 9 sí 16: Ó fọ ilé Jèhófà mọ́ 
- Ètùtù fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ 
 
- 740 Ṣ.S.K. - Samáríà pa run 
Hesekáyà ní kí gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run
- Ó ní kí àwọn sárésáré pín lẹ́tà tó fi ṣèfilọ̀ Ìrékọjá jákèjádò ilẹ̀ náà, láti Bíá-ṣébà dé Dánì 
- Àwọn kan fi wọ́n ṣẹ̀sín, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá síbi Ìrékọjá náà