March 7 Sí 13
Ẹ́SÍTÉRÌ 6-10
- Orin 131 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ẹ́sítérì Kò Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan, Ó Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀”: (10 min.) - Ẹst 8:3, 4—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí àwọn ẹlòmíì (ia ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 24 àti 25) 
- Ẹst 8:5—Ẹ́sítérì fọgbọ́n bá Ahasuwérúsì sọ̀rọ̀ (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8) 
- Ẹst 8:17—Ọ̀pọ̀ àwọn ará Páṣíà di aláwọ̀ṣe Júù (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Ẹst 8:1, 2—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ kó tó kú pé ‘Bẹ́ńjámínì yóò pín ohun ìfiṣèjẹ ní ìrọ̀lẹ́’ ṣe ṣẹ? (ia ojú ìwé 142, àpótí) 
- Ẹst 9:10, 15, 16—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fàyè gba àwọn Júù láti kó àwọn ìkógun, kí nìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀? (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: Ẹst 8:1-9 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Lẹ́yìn náà, jíròrò àpilẹ̀kọ náà “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó O Fẹ́ Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni.” 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ara sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní lẹ́yìn tí wọ́n lo ìdánúṣe láti kí àwọn tá a pè sí Ìrántí Ikú Kristi tó kọjá káàbọ̀. Ní kí ẹni tó sọ ìrírí tó gbádùn mọ́ni jù lọ ṣe àṣefihàn ìrírí rẹ̀. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 12 sí 21 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 91 (30 min.) 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 147 àti Àdúrà