ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 11-18
Ta Ló Lè Jẹ́ Àlejò Nínú Àgọ́ Jèhófà?
Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àti pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó sì ń ṣègbọràn sí i. Sáàmù ìkẹẹ̀dógún [15] sọ àwọn ohun tí Jèhófà ń wò lára ẹnì kan kó tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
ÀLEJÒ JÈHÓFÀ GBỌ́DỌ̀ . . .
- jẹ́ oníwà títọ́ 
- máa sọ òtítọ́, kódà látinú ọkàn rẹ̀ 
- máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi tiẹ̀ 
- máa ṣe ohun tó sọ, kódà tó bá tiẹ̀ nira láti ṣe bẹ́ẹ̀ 
- máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ láì máa retí ohunkóhun pa dà 
ÀLEJÒ JÈHÓFÀ KÒ GBỌ́DỌ̀ . . .
- jẹ́ olófòófó tàbí afọ̀rọ̀ èké bani jẹ́ 
- máa ṣe ohun tí kò dáa sí aládùúgbò rẹ̀ 
- máa kó àwọn ará nífà 
- bá àwọn tí kò sin Jèhófà tàbí tí wọ́n ń ṣe àìgbọràn sí i kẹ́gbẹ́ 
- gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀