July 4 Sí 10
SÁÀMÙ 60-68
- Orin 104 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà”: (10 min.) - Sm 61:1, 8—Tó o bá ṣèlérí fún Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ (w99 9/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 sí 4) 
- Sm 62:8—Tó o bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e (w15 4/15 ojú ìwé 25 àti 26 ìpínrọ̀ 6 sí 9) 
- Sm 65:1, 2—Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere (w15 4/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 13 àti 14; w10 4/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 10; it-2 ojú ìwé 668 ìpínrọ̀ 2) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Sm 63:3—Kí nìdí tí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà fi sàn ju ìyè? (w06 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7) 
- Sm 68:18—Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? (w06 6/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 63:1–64:10 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run”: (15 min.) Ẹ kọ́kọ́ jíròrò àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní A Jẹ́ Kóhun Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ ní ṣókí. Fídíò yìí wà lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW (Lọ sí WO FÍDÍÒ LÓRÍṢIRÍṢI > ÌDÍLÉ.) Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè túbọ̀ máa sin Jèhófà. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 19 ìpínrọ̀ 1 sí 16 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 88 àti Àdúrà