ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 69-73
Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́
Ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé lóòótọ́ la jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́
- Dáfídì ní ìtara fún ìjọsìn Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ 
- Dáfídì kò gbà kí ẹnikẹ́ni bá Jèhófà díje tàbí kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà 
Àwọn àgbàlagbà lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ onítara
- Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì ló kọ sáàmù yìí. Ó sọ pé ó wu òun láti fún àwọn ìran tó ń bọ̀ ní ìṣírí 
- Àwọn òbí àtàwọn Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lè dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́