August 1 Sí 7
SÁÀMÙ 87-91
- Orin 49 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Má Ṣe Kúrò Ní Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ”: (10 min.) - Sm 91:1, 2—“Ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà ń pèsè ààbò fún wa nípa tẹ̀mí (w10 2/15 ojú ìwé 26 àti 27 ìpínrọ̀ 10 àti 11) 
- Sm 91:3—Bíi ti pẹyẹpẹyẹ, Sátánì fẹ́ dẹ pańpẹ́ mú wa (w07 10/1 ojú ìwé 26 sí 30 ìpínrọ̀ 1 sí 18) 
- Sm 91:9-14—Jèhófà ni ààbò wa (w10 1/15 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 13 àti 14; w01 11/15 ojú ìwé 19 àti 20 ìpínrọ̀ 13 sí 19) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Sm 89:34-37—Májẹ̀mú wo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí, báwo sì ni Jèhófà ṣe ṣàpẹẹrẹ bó ṣe jóòótọ́ tó? (w14 10/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 14; w07 7/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 3 àti 4) 
- Sm 90:10, 12—Báwo ni a ṣe ń ‘ka àwọn ọjọ́ wa lọ́nà tí a ó fi ní ọkàn-àyà ọgbọ́n’? (w06 7/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 4; w01 11/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 19) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 90:1-17 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (5 min.) 
- “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣe Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi”: (10 min.) Ìjíròrò. Lo àwọn ìbéèrè yìí láti fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti ran ẹnì kan lọ́wọ́ débi pé onítọ̀hún ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Báwo lẹ ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ yín lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Báwo lẹ ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ yín lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 21 ìpínrọ̀ 1 sí 12 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 137 àti Àdúrà