MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Máa Dáhùn Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
Ìdáhùn tó gbéṣẹ́ máa ń gbé ìjọ ró. (Ro 14:19) Ó sì máa ṣe ẹni tó dáhùn náà láǹfààní. (Owe 15:23, 28) Torí náà, ó yẹ ká máa gbìyànjú láti dáhùn nípàdé ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan. Òótọ́ ni pé wọ́n lè má pè wá ní gbogbo ìgbà tá a bá nawọ́. Fún ìdí yìí, ó yẹ ká máa múra ju ìdáhùn kan lọ.
Ìdáhùn tó gbéṣẹ́ . . .
- máa ń ṣe tààràtà, kì í lọ́jú pọ̀, á sì ṣe ṣókí, láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀ 
- máa ń jẹ́ ìdáhùn lọ́rọ̀ ara ẹni 
- kì í ṣe àtúnsọ ohun tẹ́nì kan ti dáhùn tẹ́lẹ̀ 
Tó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n kọ́kọ́ pè, . . .
- dáhùn ìbéèrè náà ní tààràtà, kó sì ṣe ṣókí 
Bí ẹnì kan bá ti dáhùn ṣáájú, o lè . . .
- fi ẹsẹ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀ ti kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò lẹ́yìn 
- sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò ní ìgbésí ayé wa 
- ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìsọfúnni náà 
- sọ ìrírí ṣókí láti kín kókó pàtàkì náà lẹ́yìn