November 7-13
ÒWE 27-31
- Orin 86 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe”: (10 min.) - Owe 31:10-12—Ó jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán (w15 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 10; w00 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2; it-2-E ojú ìwé 1183 ìpínrọ̀ 6) 
- Owe 31:13-27—Ó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára (w00 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 àti 4) 
- Owe 31:28-31—Ó jẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀, tó yẹ kéèyàn máa gbóríyìn fún (w15 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 8; w00 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5 àti 8) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Owe 27:12—Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbọ́n tó bá dọ̀rọ̀ eré ìnàjú? (w15 7/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 3) 
- Owe 27:21—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà, “ẹnì kọ̀ọ̀kan wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìn rẹ̀”? (w11 8/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1; w06 9/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 11) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Owe 29:11–30:4 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú láti kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè”: (5 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. 
- Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (10 min.) Ẹ sì lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 ojú ìwé 40 àti 41) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 3 ìpínrọ̀ 13 sí 22, àti “Jèhófà Ń Ṣí Ète Rẹ̀ Payá Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé,” àpótí náà “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 108 àti Àdúrà