December 12-18
AÍSÁYÀ 6-10
- Orin 116 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ ”: (10 min.) - Ais 9:1, 2—Àsọtẹ́lẹ̀ ti wà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì (w11 8/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 13; ip-1 ojú ìwé 124 sí 126 ìpínrọ̀ 13 sí 17) 
- Ais 9:6—Ó máa ní ọ̀pọ̀ ojúṣe lónírúurú láti bójú tó (w14 2/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 18; w07 5/15 ojú ìwé 6) 
- Ais 9:7—Ìṣàkóso rẹ̀ máa mú àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo wá fún aráyé (ip-1 ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 28 àti 29) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Ais 7:3, 4—Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo Áhásì Ọba tó jẹ́ ẹni burúkú? (w06 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 4) 
- Ais 8:1-4—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ? (it-1-E ojú ìwé 1219; ip-1 ojú ìwé 111 àti 112 ìpínrọ̀ 23 àti 24) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 7:1-17 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn g16.6 tó wà lójú ìwé 2 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn g16.6 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv ojú ìwé 34 ìpínrọ̀ 18—Fi béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ hàn. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Èmi Nìyí! Rán Mi!” (Ais 6:8): (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní A Kó Lọ Síbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I] . 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 5 ìpínrọ̀ 10 sí 17, àpótí “Ọkàn Ti Wá Balẹ̀ Dáadáa Wàyí” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 150 àti Àdúrà - Ìránnilétí: Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.