February 13-19
Aísáyà 52-57
- Orin 148 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Kristi Jìyà fún Wa”: (10 min.) - Ais 53:3-5—Wọ́n tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ rẹ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa (w09 1/15 26 ¶3-5) 
- Ais 53:7, 8—Ó fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún wa tinútinú (w09 1/15 27 ¶10) 
- Ais 53:11, 12—Àwa náà lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run torí pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú (w09 1/15 28 ¶13) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Ais 54:1—Ta ni “àgàn tí kò bímọ” tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tọ́ka sí, àwọn wo sì ni “àwọn ọmọ” rẹ̀? (w06 3/15 11 ¶2) 
- Ais 57:15—Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun ń “gbé” pẹ̀lú “àwọn tí a tẹ̀ rẹ́” àti “àwọn ẹni rírẹlẹ̀”? (w05 10/15 26 ¶3) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 57:1-11 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) ll 6—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá. 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) ll 7—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 14-15 ¶16-17—Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jẹ́ kí bàbá kan bá ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Nínú Ẹlẹ́dàá”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò yìí Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ—Ọlọ́run Wà Lóòótọ́. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 8 ¶8-13 àti “Àtẹ Àwọn Ìwé Tí Wọ́n Ń Tẹ̀ Jáde Jù Láyé” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 107 àti Àdúrà