ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 63-66
Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun Máa Mú Ká Láyọ̀ Tó Kọ Yọyọ
Ìlérí ìmúbọ̀sípò tí Ọlọ́run ṣe nínú Aísáyà orí 65 dájú pé ó máa ṣẹ, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ ọ́ bí ohun tó ti ṣẹlẹ̀.
Jèhófà máa dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun, àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí
Kí ni ọ̀run tuntun?
- Ó jẹ́ ìjọba tuntun kan tó máa mú kí òdodo gbilẹ̀ kárí ayé 
- Ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 nígbà tí Ọlọ́run gbé Kristi gorí ìtẹ́, tó sì di Ọba Ìjọba Ọlọ́run 
Kí ni ayé tuntun?
- Àpapọ̀ àwọn èèyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè, èdè, àti ẹ̀yà tí wọ́n fayọ̀ gbà láti wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba ọ̀run tuntun 
Báwo ni àwọn ohun àtijọ́ kò ṣe ní wá sí ìrántí?
- Kò ní sí ohun tó máa mú ká rántí àwọn nǹkan tó lè bà wá nínú jẹ́ mọ́ 
- Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa gbádùn ayé wọn dọ́ba, ojoojúmọ́ ni inú wọn á máa dùn