ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 22-24
Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?
Jèhófà fi àwọn èèyàn wé èso ọ̀pọ̀tọ́
- Àwọn olóòótọ́ lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì dà bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó dára 
- Sedekáyà Ọba tó jẹ́ aláìṣòótọ́ àtàwọn míì tó hùwà búburú dà bí èso àjàrà tí kò dára 
Báwo la ṣe lè ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ Jèhófà?
- Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ sílò, Jèhófà máa fún wa ní “ọkàn-àyà láti mọ̀” ọ́n 
- A gbọ́dọ̀ yẹ ọkàn wa wò dáadáa, ká sì mú àwọn ìwà tí kò dára àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kúrò níbẹ̀