ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 49-50
Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Ó sì Ń Fìyà Jẹ Àwọn Agbéraga
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà máa fò fáyọ̀ nígbà tí Jèhófà bá mú wọn kúrò nígbèkùn
Wọ́n á tún mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ lákọ̀tun, wọ́n á sì rìnrìn àjò tó jìn pa dà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́
Bábílónì kò ní lọ láìjìyà torí ìwà ìkà tó burú jáì tó hù sí àwọn èèyàn Jèhófà
Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ní ìmúṣẹ, Bábílónì di ahoro, kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ títí dòní