August 7-13
Ìsíkíẹ́lì 28-31
Orin 85 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà San Ìlú Abọ̀rìṣà Kan Lẹ́san”: (10 min.)
Isk 29:18—Nebukadinésárì ọba Bábílónì kò gba èrè kankan fún bó ṣe ṣẹ́gun ìlú Tírè (it-2 1136 ¶4)
Isk 29:19—Ọba Nebukadinésárì gba Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ dípò Tírè (it-1 698 ¶5)
Isk 29:20—Jèhófà san àwọn ará Bábílónì lẹ́san torí pé wọ́n ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu (g86 11/8 27 ¶4-5)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Isk 28:12-19—Báwo ni ìwà tí àwọn alákòóso ìlú Tírè hù ṣe jọ irú ìwà tí Sátánì hù? (it-2 604 ¶4-5)
Isk 30:13, 14—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ? (w03 7/1 32 ¶1-3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Isk 29:1-12
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tá a wà yìí tí wọ́n bá ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀, kí wọ́n sì lo fídíò náà Ṣé O Fẹ́ Gbọ́ Ìròyìn Ayọ̀? nígbà tí wọ́n bá ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọni.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (5 min.) Tàbí kẹ́ ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb17 35-36 áti Àpótí tó wà ní ojú ìwé 35)
“Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní—Ìrẹ̀lẹ̀”: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Ìdúróṣinṣin Rẹ Jẹ́—Ìgbéraga.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr “Apá 5—Ètò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba Ọlọ́run—Bí Àwọn Ìránṣẹ́ Ọba Náà Ṣe Ń Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́, orí 16 1-5, àwọn àpótí “Ìjọsìn Ìdílé” áti “Àwọn Àpéjọ Ọdọọdún Tó Ń Mú Káwọn Èèyàn Ọlọ́run Wà Níṣọ̀kan”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 20 àti Àdúrà