September 25–October 1
DÁNÍẸ́LÌ 4-6
- Orin 67 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ṣé Ò Ń Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀?”: (10 min.) - Da 6:7-10—Dáníẹ́lì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè máa sin Jèhófà láìyẹsẹ̀ (w10 11/15 6 ¶16; w06 11/1 24 ¶12) 
- Da 6:16, 20—Ọba Dáríúsì rí i pé Dáníẹ́lì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà (w03 9/15 15 ¶2) 
- Da 6:22, 23—Jèhófà bù kún Dáníẹ́lì torí pé ó ń sìn ín láìyẹsẹ̀ (w10 2/15 18 ¶15) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Da 4:10, 11, 20-22—Kí ni arabaríbí igi inú àlá Nebukadinésárì dúró fún? (w07 9/1 18 ¶5) 
- Da 5:17, 29—Kí nìdí tí Dáníẹ́lì kò fi kọ́kọ́ gba ẹ̀bùn tí Ọba Bẹliṣásárì fún un, àmọ́ tó wá gbà á nígbà tó yá? (w88 10/1 30 ¶3-5; dp 109 ¶22) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Da 4:29-37 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) inv 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) inv—Nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún ẹni náà, o ti fún un ní ìwé ìkésíni sí àwọn ìpàdé. Ṣe ìpadàbẹ̀wò. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 120 ¶16—Fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìṣírí pé kó jẹ́ adúróṣinṣin kódà tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá ń ṣe inúnibíni sí i. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò bí akéde kan tó ní ìrírí dáadáa ṣe ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 18 ¶9-20, àpótí “Kí Là Ń Lo Àwọn Ọrẹ Wa Fún?,” àpótí tó wà fún àtúnyẹ̀wò “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 73 àti Àdúrà