January 29–February 4
MÁTÍÙ 10-11
- Orin 4 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jésù Mú Kí Ara Tù Wá”: (10 min.) - Mt 10:29, 30—Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an, èyí sì ń mú kí ara tù wá (“ológoṣẹ́,” “ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré,” “gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà” àlàyé ọ̀rọ̀ àti “Ológoṣẹ́” àwòrán àti fídíò lórí Mt 10:29, 30, nwtsty) 
- Mt 11:28—Bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà ń tù wá lára (“di ẹrù wọ̀ lọ́rùn,” “èmi yóò sì tù yín lára” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:28, nwtsty) 
- Mt 11:29, 30—Bá a ṣe ń fi ara wa sábẹ́ àṣẹ àti ìtọ́sọ́nà Kristi ń tù wá lára (“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:29, nwtsty) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Mt 11:2, 3—Kí nìdí tí Jòhánù Arinibọmi fi béèrè ìbéèrè yìí? (jy 96 ¶2-3) 
- Mt 11:16-19—Kí ni àwọn ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? (jy 98 ¶1-2) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 11:1-19 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò àti ìbéèrè fún ìgbà míì. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 42-43 ¶15-16—Pe ẹni náà wá sí ìpàdé. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Bá A Ṣe Ń Tu “Àwọn Tí Ń Ṣe Làálàá, Tí A Sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn” Nínú: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará pé: - Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó jẹ́ kí àwọn èèyàn nílò ìtura? 
- Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń lo ètò rẹ̀ láti tù wá lára? 
- Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe máa ń tù wá lára? 
- Báwo la ṣe lè mú kí ara tu àwọn ẹlòmíì? 
 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 3, ¶16-21 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 138 àti Àdúrà