March 19-25
MÁTÍÙ 24
- Orin 126 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Máa Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí”: (10 min.) - Mt 24:12—Ìwà àìlófin tó ń pọ̀ sí i máa jẹ́ kí ìfẹ́ àwọn èèyàn di tútù (it-2 279 ¶6) 
- Mt 24:39—Bí àwọn kan ṣe máa gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn ló máa gbà wọ́n lọ́kàn, tí wọn ò sì ní lè wà lójúfò (w99 11/15 19 ¶5) 
- Mt 24:44—Ọ̀gá náà máa dé nígbà tí a kò rò tẹ́lẹ̀ (jy 259 ¶5) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Mt 24:8—Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Jésù yìí tọ́ka sí? (“ìroragógó wàhálà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty) 
- Mt 24:20—Kí nìdí tí Jésù fi sọ ọ̀rọ̀ yìí? (“ní ìgbà òtútù,” “ní ọjọ́ sábáàtì” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:20, nwtsty) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 24:1-22 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín. 
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni tó o kọ́kọ́ wàásù fún kò sí nílé, àmọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan lo bá. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Òpin Ètò Àwọn Nǹkan Yìí Ti Sún Mọ́ Gan-an”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 5 ¶7-15 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 97 àti Àdúrà