April 2-8
MÁTÍÙ 26
- Orin 19 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ìyàtọ̀ àti Ìjọra Tó Wà Láàárín Ìrékọjá àti Ìrántí Ikú Kristi”: (10 min.) - Mt 26:17-20—Jésù jẹ Ìrékọjá tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ (“Oúnjẹ Ìrékọjá” àwòrán àti fídíò lórí Mt 26:18, nwtsty) 
- Mt 26:26—Búrẹ́dì tá a máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ ara Jésù (“túmọ̀ sí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:26, nwtsty) 
- Mt 26:27, 28—Wáìnì tá a máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” Jésù (“ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:28, nwtsty) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Mt 26:17—Kí nìdí tí wọ́n fi pe Nísàn 13 ní “ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú”? (“Ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:17, nwtsty) 
- Mt 26:39—Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Jésù gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá”? (“jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:39, nwtsty) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 26:1-19 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 55 ¶21-22 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (8 min.) 
- Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Ìràpadà: (7 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n pé: Kí nìdí tàwọn èèyàn fi ń ṣàìsàn, tí wọ́n ń darúgbó, tí wọ́n sì ń kú? Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe? Ta lo máa fẹ́ rí nínú Párádísè? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv àfikún “Kíkí Àsíá, Dídìbò àti Sísin Ìlú Ẹni” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 74 àti Àdúrà