April 16-22
MÁÀKÙ 1-2
- Orin 130 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”: (10 min.) - [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Máàkù.] 
- Mk 2:3-5—Àánú sún Jésù láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ọkùnrin arọ kan (jy 67 ¶3-5) 
- Mk 2:6-12—Bí Jésù ṣe wo ọkùnrin arọ yẹn sàn fi hàn pé ó ní àṣẹ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini (“Èwo ni ó rọrùn jù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 2:9, nwtsty) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Mk 1:11—Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jésù yìí túmọ̀ sí? (“ohùn kan sì wá láti inú àwọsánmà,” “Ìwọ ni Ọmọ mi,” “mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 1:11, nwtsty) 
- Mk 2:27, 28—Kí nìdí tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní “Olúwa . . . sábáàtì”? (“Olúwa . . . sábáàtì” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 2:28, nwtsty) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 1:1-15 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín. 
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Èmi Kò Wá Láti Pe Àwọn Olódodo, Bí Kò Ṣe Àwọn Ẹlẹ́ṣẹ̀”: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Mo Rìnnà Kore Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Báwo ni Donald ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù kì í ṣe é ṣojúsàájú tá a bá ń wàásù?—Mk 2:17. 
- Jèhófà Máa Ń Dárí Jì “Lọ́nà Títóbi”: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Jèhófà, Ìwọ Ni Màá Fi Sípò Àkọ́kọ́ Nígbèésí Ayé Mi. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Báwo ni Anneliese ṣe pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí sì nìdí? (Ais 55:6, 7) Báwo lo ṣe lè fi ìrírí yìí ran àwọn tó ti ń fi Jèhófà sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ lọ́wọ́? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 6 ¶10-15 àti àpótí “Irú Eré Ìnàjú Wo Ló Yẹ Kí N Yàn?” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 86 àti Àdúrà