April 23-29
MÁÀKÙ 3-4
- Orin 77 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jésù Ṣe Ìwòsàn ní Ọjọ́ Sábáàtì”: (10 min.) - Mk 3:1, 2—Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ń ṣọ́ Jésù, kí wọ́n lè wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀ (jy 78 ¶1-2) 
- Mk 3:3, 4—Jésù mọ̀ pé wọ́n ní èrò òdì tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nípa òfin Sábáàtì (jy 78 ¶3) 
- Mk 3:5—Jésù ní “ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn-àyà wọn” (“pẹ̀lú ìkannú, nítorí tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 3:5, nwtsty) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Mk 3:29—Kí ló túmọ̀ sí láti sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kí sì ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa yọrí sí? (“ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́,” “ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 3:29, nwtsty) 
- Mk 4:26-29—Kí la lè rí kọ́ nínú àpèjúwe Jésù nípa afúnrúgbìn tó sùn? (w14 12/15 12-13 ¶6-8) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 3:1-19a 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò, fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 34-36 ¶21-22—Fi béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ hàn. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Kí Ẹni Tí Ó Ní Etí Láti Fetí Sílẹ̀, Fetí Sílẹ̀”: (15 min.) Sọ ohun tí Máàkù 4:9 túmọ̀ sí (“Kí Ẹni Tí Ó Ní Etí Láti Fetí Sílẹ̀, Fetí Sílẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 4:9, nwtsty). Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Wàá Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Tó O Bá Ń Gbàmọ̀ràn. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ jíròrò Àpótí “Fetí Sí Ìmọ̀ràn Kí O Sì Gba Ìbáwí” nínu ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ ojú ìwé 46-47. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 6 ¶16-23 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 123 àti Àdúrà