June 25–July 1
Lúùkù 4-5
- Orin 37 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù”: (10 min.) - Lk 4:1-4—Jésù kò gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara láyè (w13 8/15 25 ¶8) 
- Lk 4:5-8—Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú kò gba Jésù lọ́kàn (w13 8/15 25 ¶10) 
- Lk 4:9-12—Jésù kò tiẹ̀ gbìyànjú láti ṣe àṣehàn [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Odi Orí Òrùlé Tẹ́ńpìlì.] (“Odi Orí Òrùlé Tẹ́ńpìlì” fídíò àti àwòrán lórí Lk 4:9-12, nwtsty; w13 8/15 26 ¶12) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Lk 4:17—Kí ló fi hàn pé Jésù mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa? (“àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 4:17, nwtsty) 
- Lk 4:25—Báwo ni ọ̀dá tó wáyé nígbà ayé Èlíjà ṣe gùn tó? (“fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 4:25, nwtsty) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 4:31-44 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Kó o wá fún un ní káàdì ìkànnì JW.ORG. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò, fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jl ẹ̀kọ́ 28 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 9 ¶13-21 àti Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú? 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 105 àti Àdúrà