August 13-19
Lúùkù 19-20
Orin 84 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá”: (10 min.)
Lk 19:12, 13—“Ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá” sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣòwò títí tóun máa fi ti ìrìn àjò dé (jy 232 ¶2-4)
Lk 19:16-19—Ohun táwọn ẹrú tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lè ṣe yàtọ̀ síra, àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló gba èrè (jy 232 ¶7)
Lk 19:20-24—Ẹrú burúkú tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ pàdánù ohun tó ní (jy 233 ¶1)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Lk 19:43—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí ṣe ṣẹ? (“àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 19:43, nwtsty)
Lk 20:38—Báwo ni ohun tí Jésù sọ ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àjíǹde máa wáyé lóòótọ́? (”gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 20:38, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 19:11-27
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w14 8/15 29-30—Àkòrí: Ṣé Àjíǹde Orí Ilẹ̀ Ayé Ni Jésù Ń Tọ́ka Sí Nínú Lúùkù 20:34-36?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò náà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 11 ¶20-22, àti Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Mi Sunwọ̀n Sí I?.
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 116 àti Àdúrà