ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 August ojú ìwé 7
  • Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú Ìjọ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Má Ṣe Mú Kí “Àwọn Ẹni Kékeré Yìí” Kọsẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 August ojú ìwé 7
Jésù ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà

Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún àwa èèyàn aláìpé. (Ro 5:8) Abájọ tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi mọ rírì ìfẹ́ tí Jésù fi hàn nípa bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ni Kristi kú fún. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìpé bíi tiwa? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, a lè yan àwọn míì lọ́rẹ̀ẹ́, irú bíi àwọn tí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ sí tiwa. (Ro 15:7; 2Kọ 6:​12, 13) Ìkejì ni pé, ó yẹ ká máa ṣọ́ra ká má bàa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó máa bí àwọn míì nínú. (Ro 14:​13-15) Ní paríparí ẹ̀, tí àwọn míì bá ṣẹ̀ wá, ó yẹ ká máa tètè dárí jì wọ́n. (Lk 17:​3, 4; 23:34) Tá a bá sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní àwọn ọ̀nà yìí, Jèhófà máa jẹ́ kí ìjọ wà ní ìṣọ̀kan àti ní àlááfíà.

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA SUNWỌ̀N SÍ I LÓJOOJÚMỌ́! KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ará ń kí Miki káàbọ̀ sínú ìjọ tuntun tó wá

    Èrò wo ni Miki kọ́kọ́ ní nípa ìjọ rẹ̀?

  • Inú ń bí Miki sí ohun táwọn ará ń ṣe nínú ìjọ

    Kí ló mú kí èrò rẹ̀ yí pa dà?

  • Jésù ṣì fàánú hàn sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sùn

    Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe ran Miki lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́? (Mk 14:38)

  • Miki rẹ́rìn-ín nígbà tí ọmọkùnrin kékeré kan ta lù ú, tó sì jẹ́ kí ohun tó gbẹ́ dání dà sí i láṣọ

    Báwo ni Òwe 19:11 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?

FI ṢE ÀṢÀRÒ:

Ṣé ohun kan ṣì wà tẹ́nì kan ṣe fún mi tó dùn mí gan-an àmọ́ tó yẹ kí n gbé kúrò lọ́kàn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́