MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni ọkùnrin títóbi jù lọ tó gbé ayé rí, síbẹ̀ ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ torí pé Jèhófà ló máa ń fògo fún. (Jo 7:16-18) Lọ́wọ́ kejì, Sátánì ló di Èṣù, tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” (Jo 8:44) Ìwà burúkú Sátánì yìí náà làwọn Farisí máa ń hù, ìgbéraga wọn pọ̀ débi pé wọn máa ń fojú kéré àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà. (Jo 7:45-49) Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù tí wọ́n bá fún wa láǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?
- Kí ni Adé sọ tó fi hàn pé ó jẹ́ agbéraga? 
- Báwo ni Adé ṣe fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? - Báwo ni Adé ṣe fún Báyọ̀ àti Kọ́lá níṣìírí? 
- Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀? 
- Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀? - Ẹ̀kọ́ wo ni Fèyí rí kọ́ nípa bí Arákùnrin Adú ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀?