MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Kọ Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìbínú Sílẹ̀
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Jésù sọ pé ìfẹ́ la máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jo 13:34, 35) Tá a bá fẹ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, àfi ká máa wá bí nǹkan ṣe máa dáa fún wọn, ká sì máa mú sùúrù fún wọn.—1Ko 13:5.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
- Tí ẹnì kan bá ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ tàbí tó sọ̀rọ̀ tó múnú bí ẹ, ní sùúrù, ro ohun tó fà á àti ohun tó ṣe é ṣe kó tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tó o bá ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ.—Owe 19:11 
- Rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, nígbà míì a máa ń ṣe ohun tá a máa kábàámọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn 
- Tètè yanjú èdèkòyédè 
- Báwo ni Láńre ṣe gba ọ̀rọ̀ tí Tọ̀míwá sọ sódì? 
- Báwo ni sùúrù ṣe ran Tọ̀míwá lọ́wọ́ láti má ṣe gbaná jẹ? 
- Báwo ni ọ̀rọ̀ tútù tí Tọ̀míwá sọ ṣe paná wàhálà tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀? 
Àǹfààní wo la máa ṣe ìjọ tá ò bá gbaná jẹ tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?