October 29–November 4
JÒHÁNÙ 18-19
- Orin 54 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́”: (10 min.) - Jo 18:36—Orí Ìjọba Mèsáyà ni òtítọ́ dá lé 
- Jo 18:37—Jésù jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé (“jẹ́rìí sí,” “òtítọ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 18:37, nwtsty) 
- Jo 18:38a—Ó hàn pé Pílátù ò gbà pé nǹkan kan wà tó ń jẹ́ òtítọ́ (“Kí ni òtítọ́?” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 18:38a, nwtsty) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Jo 19:30—Kí ló túmọ̀ sí pé Jésù “jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́”? (“ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 19:30, nwtsty) 
- Jo 19:31—Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jésù kú? (“ọjọ́ Sábáàtì yẹn jẹ́ ọjọ́ ńlá” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Joh 19:31, nwtsty) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jo 18:1-14 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fi ìkànnì jw.org han onílé. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Bíbélì àti ìbéèrè fún ìgbà míì. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 14 ¶6-7 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Òtítọ́”: (15 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà “Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”—Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Òtítọ́, Kì Í Ṣe Lórí Àìṣòdodo. Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà “Ṣàṣàrò Lórí Àpẹẹrẹ Inú Bíbélì.” 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 15 ¶1-9 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 32 àti Àdúrà