November 26–December 2
Ìṣe 6-8
- Orin 124 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ìjọ Kristẹni Tuntun Kojú Ìṣòro”: (10 min.) - Iṣe 6:1—Ó fẹ́ jọ pé àwọn kan nínú ìjọ ń gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Gíríìkì nítorí ẹ̀yà wọn (bt 41 ¶17) 
- Iṣe 6:2-7—Àwọn àpọ́sítélì bójú tó ìṣòro náà (bt 42 ¶18) 
- Iṣe 7:58–8:1—Wọ́n ṣe inúnibíni ńláǹlà sí ìjọ 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Iṣe 6:15—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé ojú Sítéfánù rí “bí ojú áńgẹ́lì”? (bt 45 ¶2) 
- Iṣe 8:26-30—Lóde òní, ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni gbà láǹfààní láti ṣe irú iṣẹ́ tí Fílípì ṣe? (bt 58 ¶16) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Iṣe 6:1-15 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Kó o sì pe ẹni náà wá sí ìpàdé. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ ìwé mímọ́ tó o máa lò, fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 33 ¶16-17 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”: (15 min.) Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ẹ kọ́kọ́ wo fídíò náà ‘Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà’. Ka lẹ́tà tó wá látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n fi ń dúpẹ́ fún àwọn ọrẹ tí wọ́n rí gbà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Sọ àwọn àǹfààní tá a máa rí bá a ṣe ń ṣe ọrẹ. Sọ àwọn ohun tí ìjọ máa ń náwó lé lóṣooṣù. Jíròrò bá a ṣe lè ṣe ọrẹ àti ohun tí wọ́n ń lo àwọn ọrẹ náà fún. Gbóríyìn fún ìjọ fún àwọn ọrẹ tí wọ́n fi ń ṣe ìtìlẹ́yìn. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 16 ¶9-14, àti àpótí Ṣọ́ra Fún Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Sátánì! 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 67 àti Àdúrà