March 25-31
1 KỌ́RÍŃTÌ 4-6
- Orin 123 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ìwúkàrà Díẹ̀ Ní Í Mú Gbogbo Ìṣùpọ̀ Di Wíwú”: (10 min.) - 1Kọ 5:1, 2—Àwọn tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì ń fàyè gba oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà 
- 1Kọ 5:5-8, 13—Pọ́ọ̀lù sọ pé kí ìjọ yọ “ìwúkàrà” náà kúrò láàárín wọn, kí wọ́n sì fi ẹni tó hùwà àìtọ́ náà lé Sátánì lọ́wọ́ (it-2 230, 869-870) 
- 1Kọ 5:9-11—Ẹnì kankan nínu ìjọ ò gbọdọ̀ bá oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà náà kẹ́gbẹ́ (lv 207 ¶1-3, àfikún “Ọwọ́ Tó Yẹ Ká Fi Mú Ẹni Tí Wọ́n Bá Yọ Lẹ́gbẹ́.”) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - 1Kọ 4:9—Báwo ni àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe di “ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran” fún àwọn áńgẹ́lì? (w09 5/15 24 ¶16) 
- 1Kọ 6:3—Kí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwa ni yóò ṣèdájọ́ àwọn áńgẹ́lì”? (it-2 211) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Kọ 6:1-14 (th ẹ̀kọ́ 10) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 11) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 207 ¶2, 3 (th ẹ̀kọ́ 3) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Fídíò náà jẹ́ ká rí bí akéde kan ṣe fi fídíò tó dá lórí ẹ̀kọ́ 4 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ kọ́ ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 4 ¶10-11 àti àfikún “Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé.” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 23 àti Àdúrà