MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bí Gbogbo Wa Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa kì í ṣe ilé kan lásán; ibi tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ti ń jọ́sìn rẹ̀ ni. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁ A ṢE LÈ MÁA BÓJÚ TÓ ÀWỌN IBI ÌJỌSÌN WA, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Kí la máa ń ṣe ní ibi tá a ti máa ń ṣe ìpàdé? 
- Kí nìdí tó fi yẹ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, ká sì máa ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó bà jẹ́? 
- Àǹfààní wo lo rí nígbà tó o lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba? 
- Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe nǹkan tó máa ṣe wá léṣe, àpẹẹrẹ wo lo rí nínú fídíò náà? 
- Báwo la ṣe lè fi àwọn ọrẹ wa bọlá fún Jèhófà? 
BÁWO NI MO ṢE FẸ́ TI IṢẸ́ YÌÍ LẸ́YÌN?