July 8-14
1 TẸSALÓNÍKÀ 1-5
- Orin 90 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ẹ Máa Fún Ara Yín Níṣìírí, Kí Ẹ sì Máa Gbé Ara Yín Ró”: (10 min.) - [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní.] 
- 1Tẹ 5:11-13—Ẹ máa ka àwọn tó ń ṣe àbójútó yín sí “lọ́nà àrà ọ̀tọ̀” (w11 6/15 26 ¶12; 28 ¶19) 
- 1Tẹ 5:14—Ẹ sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ ran àwọn aláìlera lọ́wọ́ (w17.10 10 ¶13; w15 2/15 9 ¶16) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - 1Tẹ 4:3-6—Ọ̀nà wo ni ẹni tó ṣe ìṣekúṣe gbà “yan arákùnrin rẹ̀ jẹ”? it-1 863-864) 
- 1Tẹ 4:15-17—Àwọn wo la máa ‘gbà lọ nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́,’ báwo ló sì ṣe máa ṣẹlẹ̀? (w15 7/15 18-19 ¶14-15) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Tẹ 3:1-13 (th ẹ̀kọ́ 5) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1) 
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3) 
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 4) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Ń Fún Àwọn Míì Níṣìírí: (9 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Ṣe Bẹbẹ. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe lè fún àwọn ará ìjọ níṣìírí? Ìṣírí wo lo ti rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà nínú ìjọ rẹ? 
- Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Tó Lè Fún Wa Níṣìírí: (6 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà A Gbọ́dọ̀ ‘Fi Ìfaradà Sáré’—Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àpẹẹrẹ Rere. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Ìṣòro wo ni arábìnrin yẹn ní? Kí ló ṣe tó fi rí ìṣírí gbà? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 8 ¶1-7 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 100 àti Àdúrà