MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Lo Máa Ṣe Ní Ọdún Ọ̀gbẹlẹ̀?
Ó ṣe pàtàkì kéèyàn nígbàgbọ́ kó tó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbàgbọ́ tó lágbára máa jẹ́ ká gbà pé Jèhófà máa dáàbò bò wá, á sì bójú tó wa. (Sm 23:1, 4; 78:22) Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ayé yìí, a mọ̀ pé àwọn àdánwò Sátánì á túbọ̀ máa le sí i. (Ifi 12:12) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KÍ LO MÁA ṢE NÍ ỌDÚN Ọ̀GBẸLẸ̀? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Báwo la ṣe dà bí “igi” tá a mẹ́nu kàn nínú Jeremáyà 17:8? 
- Kí ni ọ̀kan lára ohun tó lè dà bí “ooru”? 
- Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí “igi” náà, kí sì nìdí? 
- Kí ni Sátánì fẹ́ bà jẹ́? 
- Báwo la ṣe dà bí àwọn tó ti ń wọkọ̀ òfúrufú tipẹ́? 
- Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye, àmọ́ kí ló lè dán wa wò? 
- Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán àwọn ìlànà Bíbélì láìka ohun táwọn èèyàn lè máa sọ?