ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 20-22
“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo di Tuntun”
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa sọ ohun gbogbo di tuntun.
- “Ọ̀run tuntun”: Ìjọba tuntun kan tó máa mú kí òdodo gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé 
- “Ayé tuntun”: Àwọn èèyàn tó fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wọn 
- “Ohun gbogbo di tuntun”: Gbogbo ẹ̀dùn ọkàn, ìrora àtàwọn nǹkan míì tó ń fa ìbànújẹ́ máa pòórá, ojoojúmọ́ sì ni ìgbésí ayé wa á máa dùn bí oyin