ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 3-5
Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́
Àtìgbà tí Sátánì ti parọ́ fún Éfà ló ti ń ṣi aráyé lọ́nà. (Ifi 12:9) Báwo làwọn irọ́ tí Sátánì pa tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣe mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jèhófà?
- Kò sí Ọlọ́run 
- Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run 
- Ọlọ́run ò lórúkọ 
- Ọlọ́run máa fi iná ọ̀run àpáàdì dá àwọn èèyàn lóró títí láé 
- Àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa 
- Ọlọ́run ò rí tiwa rò 
Báwo làwọn irọ́ yìí ṣe rí lára rẹ?
Kí lo lè ṣe láti gbèjà orúkọ Ọlọ́run?