FEBRUARY 17-23
JẸ́NẸ́SÍSÌ 18-19
Orin 1 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“‘Onídàájọ́ Gbogbo Ayé’ Pa Sódómù àti Gòmórà Run”: (10 min.)
Jẹ 18:23-25—Ọkàn Ábúráhámù balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo (w17.04 18 ¶1)
Jẹ 18:32—Jèhófà fi dá Ábúráhámù lójú pé òun ò ní pa ìlú Sódómù run tí òun bá rí olódodo mẹ́wàá níbẹ̀ (w18.08 30 ¶4)
Jẹ 19:24, 25—Jèhófà pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run torí ìwà búburú wọn (w10 11/15 26 ¶12)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 18:1, 22—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “fara hàn” Ábúráhámù, tó sì tún “wà pẹ̀lú” rẹ̀? (w88 5/15 23 ¶4-5)
Jẹ 19:26—Kí nìdí tí ìyàwó Lọ́ọ̀tì fi di “ọwọ̀n iyọ̀”? (w19.06 20 ¶3)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 18:1-19 (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni akéde náà ṣe nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó dára? Báwo ló ṣe jẹ́ kí onílé lóye ohun tó kà nínú ẹsẹ Bíbélì náà?
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 6)
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? kó o sì ṣàlàyé àwòrán tó wà lójú ìwé 98. (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ẹ Má Ṣe Máa Nífẹ̀ẹ́ Ayé (1Jo 2:15).
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 16 ¶1-8
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 2 àti Àdúrà