March 30–April 5
JẸ́NẸ́SÍSÌ 29-30
- Orin 93 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jékọ́bù Fẹ́ Ìyàwó”: (10 min.) - Jẹ 29:18-20—Jékọ́bù gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje kó lè fẹ́ Réṣẹ́lì (w03 10/15 29 ¶5) 
- Jẹ 29:21-26—Lábánì tan Jékọ́bù, ó fún un ní Líà dípò Réṣẹ́lì (w07 10/1 8-9; it-2 341 ¶3) 
- Jẹ 29:27, 28—Jékọ́bù ṣe ohun tó dáa nínú ipò tí kò rọrùn 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Jẹ 30:3—Kí nìdí tí Réṣẹ́lì fi ka ọmọ tí Bílíhà bí fún Jékọ́bù sí ọmọ òun? (it-1 50) 
- Jẹ 30:14, 15—Kí nìdí tí Réṣẹ́lì fi torí èso máńdírékì yááfì àǹfààní tó ní láti sùn ti ọkọ rẹ̀ kó lè lóyún? (w04 1/15 28 ¶7) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 30:1-21 (th ẹ̀kọ́ 2) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni: (10 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 16 nínú ìwé pẹlẹbẹ Kíkọ́ni. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bhs 59 ¶21-22 (th ẹ̀kọ́ 18) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Wàásù fún Àwọn Afọ́jú”: (10 min.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fí ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn afọ́jú lọ́wọ́? Ibo la ti lè rí àwọn afọ́jú? Báwo la ṣe lè bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè kí àwọn afọ́jú lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà? 
- Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe: (5 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù March. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 17 ¶13-17 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 30 àti Àdúrà