May 4-10
JẸ́NẸ́SÍSÌ 36-37
- Orin 114 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀”: (10 min.) - Jẹ 37:3, 4—Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kórìíra rẹ̀ torí pé òun ni bàbá wọn fẹ́ràn jù (w14 8/1 12-13) 
- Jẹ 37:5-9, 11—Àwọn àlá tí Jósẹ́fù lá túbọ̀ mú káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa jowú rẹ̀ (w14 8/1 13 ¶2-4) 
- Jẹ 37:23, 24, 28—Torí pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ń jowú rẹ̀, wọ́n hùwà ìkà sí i 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Jẹ 36:1—Kí nìdí tí Bíbélì tún fi pe Ísọ̀ ní Édómù? (it-1 678) 
- Jẹ 37:29-32—Kí nìdí táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe fi aṣọ Jósẹ́fù tó ti ya, tí ẹ̀jẹ̀ sí wà lára rẹ̀ han Jékọ́bù? (it-1 561-562) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 36:1-19 (th ẹ̀kọ́ 5) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni: (10 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 17 nínú ìwé pẹlẹbẹ Kíkọ́ni. 
- Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w02 10/15 30-31—Àkòrí: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Káwa Kristẹni Máa Jowú Lọ́nà Tó Tọ́? (th ẹ̀kọ́ 6) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀?”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ẹ wo fídíò Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù? Mẹ́nu kan àwọn ìtọ́ni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fún un yín àtèyí tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fohùn ṣọ̀kan lé lórí, ìyẹn tó bá wà. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 18 ¶23-25 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 84 àti Àdúrà