July 13-19
Ẹ́KÍSÓDÙ 8-9
Orin 12 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Fáráò Agbéraga Ò Mọ̀ Pé Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Ni Òun Ń Ṣe”: (10 min.)
Ẹk 8:15—Fáráò mú ọkàn rẹ̀ le, kò sì fetí sí Mósè àti Áárónì (it-2 1040-1041)
Ẹk 8:18, 19—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà onídán Íjíbítì ò lè ṣe ohun tí Mósè àti Áárónì ṣe, síbẹ̀ Fáráò ṣagídí.
Ẹk 9:15-17—Kí Jèhófà lè ṣe orúkọ rẹ̀ lógo, ó dá ẹ̀mí Fáráò sí (it-2 1181 ¶3-5)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 8:25-27—Kí nìdí tí Mósè fi sọ pé “àwọn ará Íjíbítì máa kórìíra” ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ fi rúbọ? (w04 3/15 25 ¶10)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 8:1-19 (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni akéde náà ṣe fèsì nígbà tí onílé yẹn ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù? Kí ni akéde náà lè sọ tó bá fẹ́ fún onílé ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́?
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 6)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́. (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀—Má Ṣe Máa Fọ́nnu”: (7 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀. Lẹ́yìn náà, tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọdé, pe àwọn bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n nípa fídíò náà.
“Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́”: (8 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà Jẹ́ Adúróṣinṣin Bíi Jésù—Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Yìn Ọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 123 àti àpótí ojú ìwé 282
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 44 àti Àdúrà