MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́
Nígbà míì, àwọn èèyàn lè gbóríyìn fún wa torí ohun tá a ṣe. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè fún wa níṣìírí. (Owe 15:23; 31:10, 28) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyẹn kó sí wa lórí débi tá a fi máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ.
WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI JÉSÙ—NÍGBÀ TÍ WỌ́N BÁ Ń YÌN Ọ́, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Kí làwọn nǹkan tó lè mú káwọn èèyàn máa gbóríyìn fún wa? 
- Báwo ni àwọn ará ṣe gbóríyìn fún Arákùnrin Ṣẹ́gun? 
- Báwo ni wọ́n ṣe yin Arákùnrin Ṣẹ́gun ju bó ṣe yẹ lọ? 
- Kí lo rí kọ́ nínú bí Arákùnrin Ṣẹ́gun ṣe fèsì?