ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 27-28
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nípa Aṣọ Àlùfáà
Aṣọ táwọn àlùfáà máa ń wọ̀ rán wa létí pé ó ṣe pàtàkì ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ká jẹ́ mímọ́, ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì máa sá fún ohun tó máa tàbùkù sí Jèhófà.
- Báwo la ṣe lè máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà? 
- Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ mímọ? 
- Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì máa sá fún ohun tó máa tàbùkù sí orúkọ Jèhófà?