NOVEMBER 2-8
Ẹ́KÍSÓDÙ 39-40
- Orin 89 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Mósè Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni Tí Jèhófà Fún Un”: (10 min.) - Ẹk 39:32—Gbogbo ohun tí Jèhófà ní kí Mósè ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn ló ṣe (w11 9/15 27 ¶13) 
- Ẹk 39:43—Mósè ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ náà lẹ́yìn tí wọ́n parí rẹ̀ 
- Ẹk 40:1, 2, 16—Ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn lórí bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn náà ni wọ́n tẹ̀ lé (w05 7/15 27 ¶3) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Ẹk 39:34—Ibo ló ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rí awọ séálì tí wọ́n lò fún àgọ́ ìjọsìn? (it-2 884 ¶3) 
- Ẹk 40:34—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí ìkùukùu wà lórí àgọ́ ìpàdé? (w15 7/15 21 ¶1) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 39:1-21 (th ẹ̀kọ́ 5) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, àmọ́ ẹ dá a dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, ẹ jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ lè ṣe tá á fi hàn pé a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, tí onílé bá dá ọ̀rọ̀ òṣèlú sílẹ̀ tàbí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. 
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè onílé nígbà tó béèrè ọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèlú tàbí nípa olóṣèlú kan. (th ẹ̀kọ́ 12) 
- Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w16.04 23 ¶8-10—Àkòrí: Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú ọkàn wa àti ọ̀rọ̀ wa? (th ẹ̀kọ́ 14) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Máa Tẹ́tí Silẹ̀ Dáadáa (Mt 13:16): (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa? Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kéèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà nìkan ò tó? Kí ni ìtumọ̀ ohun tó wà nínú Máàkù 4:23, 24? Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe ohun tó wà nínú Hébérù 2:1? Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fetí sílẹ̀ dáadáa? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jy orí 139 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 139 àti Àdúrà