November 9-15
LÉFÍTÍKÙ 1-3
- Orin 20 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Mú Ọrẹ Wá”: (10 min.) - [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù.] 
- Le 1:3; 2:1, 12—Ìdí tí wọ́n fi ń rú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà (it-2 525; 528 ¶4) 
- Le 3:1—Ìdí tí wọ́n fi ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ (it-2 526 ¶1) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Le 2:13—Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ? (Isk 43:24; w04 5/15 22 ¶1) 
- Le 3:17—Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa? (it-1 813; w04 5/15 22 ¶2) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 1:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, àmọ́ ẹ dá a dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, ẹ jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ. 
- Ìpadàbẹ̀wò: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 2) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 11) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “ ‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà ‘Wọ́n Mú Ẹ̀bùn Wá fún Jèhófà’. Ka lẹ́tà tó wá látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n fi ń dúpẹ́ àwọn ọrẹ tí wọ́n rí gbà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jy ojú ìwé 317 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 120 àti Àdúrà