November 23-29
LÉFÍTÍKÙ 6-7
Orin 46 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tá A Mú Wá Láti Dúpẹ́”: (10 min.)
Le 7:11, 12—Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ jẹ́ ẹbọ táwọn èèyàn máa ń rú láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà (w19.11 22 ¶9)
Le 7:13-15—Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹni tó ń rú ẹbọ náà àti ìdílé rẹ̀ ń jẹun pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ (w00 8/15 15 ¶15)
Le 7:20—Kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ (w00 8/15 19 ¶8)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Le 6:13—Kí lèrò àwọn Júù nípa iná tó ń jó lórí pẹpẹ, àmọ́ kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? (it-1 833 ¶1)
Le 6:25—Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀? (si 27 ¶15)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 6:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Sọ̀rọ̀ lórí kókó kan látinú Ilé Ìṣọ́ No. 2 2020, kó o sì fún onílé ní ìwé ìròyìn náà. (th ẹ̀kọ́ 3)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ní kí onílé lọ sórí ìkànnì wa, kó o sì fún un ní káàdì ìkànnì jw.org. (th ẹ̀kọ́ 11)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bhs 178-179 ¶12-13 (th ẹ̀kọ́ 6)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jẹ́ Ẹni Tó Moore: (5 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n ní ìbéèrè nípa fídíò náà.
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (10 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) rr orí 1 ¶1-7 àti fídíò ohun tó wà ní orí 1a
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 37 àti Àdúrà
a Orí kọ̀ọ̀kan ìwé yìí ló ní fídíò, ẹ kọ́kọ́ wo fídíò yìí kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò orí náà.