December 14-20
LÉFÍTÍKÙ 12-13
- Orin 140 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Òfin Nípa Àrùn Ẹ̀tẹ̀”: (10 min.) - Le 13:4, 5—Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀ (wp18.1 7) 
- Le 13:45, 46—Ẹni tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn kó má bàa kó o ràn wọ́n (wp16.4 9 ¶1) 
- Le 13:52, 57—Wọ́n gbọ́dọ̀ sun ohunkóhun tí àrùn náà bá wà lára ẹ̀ (it-2 238 ¶3) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Le 12:2, 5—Kí nìdí tọ́mọ bíbí fi máa ń sọ àwọn obìnrin di “aláìmọ́”? (w04 5/15 23 ¶2) 
- Le 12:3—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ kẹjọ ni Jèhófà ní kí wọ́n dádọ̀dọ́ ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí? (wp18.1 7) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 13:9-28 (th ẹ̀kọ́ 5) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Ìjíròrò. E wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni Tóyìn ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó yẹ? Báwo ló ṣe jẹ́ kí onílé lóye ẹsẹ Bíbélì tó kà? 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 19) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ 11. (th ẹ̀kọ́ 9) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) rr orí 2 ¶1-9 àti fídíò ohun tó wà ní orí 2 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 28 àti Àdúrà