August 9-15
DIUTARÓNÓMÌ 24-26
- Orin 137 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Òfin Tí Jèhófà Ṣe Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Obìnrin”: (10 min.) 
- Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.) - Di 24:1—Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbà pé òfin yìí á jẹ́ kó rọrùn fún ọkọ kan láti kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀? (it-1 640 ¶5) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min.) Di 26:4-19 (th ẹ̀kọ́ 10) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 1) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún ẹni náà ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 2) 
- Àsọyé: (5 min.) w19.06 23-24 ¶13-16—Àkòrí: Báwo La Ṣe Lè Dúró Ti Ẹni Tí Ọkọ Tàbí Aya Ẹ̀ Kú? (th ẹ̀kọ́ 20) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Máa Hùwà Sáwọn Àgbà Obìnrin Bí Ìyá, Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin Bí Ọmọ Ìyá”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Opó Àtàwọn Ọmọ Aláìníbaba. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 12 ¶1-6, fídíò ohun tó wà ní orí 12 àti àpótí 12A 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) 
- Orin 101 àti Àdúrà