MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Jẹ́ Káwọn Míì Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Jèhófà máa ń lo àwọn “ará” wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti fún wa lókun. (1Pe 5:9) Wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, lára wọn ni Ákúílà àti Pírísílà, Sílà, Tímótì àtàwọn míì.—Iṣe 18:1-5.
Báwo làwọn míì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Wọ́n lè fún wa nímọ̀ràn lórí bá a ṣe lè fèsì tẹ́nì kan bá ta ko ọ̀rọ̀ wa, bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò àti bá a ṣe lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ronú nípa ẹnì kan nínú ìjọ yín tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó dájú pé ẹ̀yin méjèèjì ló máa ṣe láǹfààní, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ láyọ̀.—Flp 1:25.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—MÁA LO ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ PÈSÈ—ÀWỌN ARÁ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Àwọn nǹkan wo ni Neeta ṣe kó lè pe Jade wá sípàdé? 
- Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mú àwọn míì lọ sọ́dọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa? 
- Gbogbo ìjọ ló ń sọ ẹnì kan di ọmọ ẹ̀yìn - Kí ló fa Jade mọ́ra nípa Arábìnrin Abigay? 
- Àwọn nǹkan wo lo lè kọ́ lára àwọn míì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?