January 10-16
ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 17-19
- Orin 88 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Téèyàn Bá Rú Òfin Ọlọ́run, Àbájáde Ẹ̀ Kì Í Dáa”: (10 min.) 
- Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.) - Ond 19:18—Kí nìdí tá a ṣe fi orúkọ Jèhófà sínú ẹsẹ Bíbélì yìí nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013 (w15 12/15 10 ¶6) 
- Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ond 17:1-13 (th ẹ̀kọ́ 2) 
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ìpadàbẹ̀wò: Ọlọ́run Ń Bójú Tó Wa—Jer 29:11. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ. 
- Ìpadàbẹ̀wò: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 6) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún ẹni náà ní ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀kọ́ 01. (th ẹ̀kọ́ 13) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Ṣègbọràn sí Àwọn Òbí Rẹ: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ wọn: Kí ni mọ́mì Kọ́lá ní kó ṣe àmọ́ tí kò ṣe? Kí ni Kọ́lá ṣe tó fi hàn pé ó ṣàtúnṣe? Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu? 
- Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (5 min.) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 18 ¶16-25 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) 
- Orin 150 àti Àdúrà